Full Lyrics
CHORUS
Wá gb'ọrẹ wá o Bàbá
Wá gb'ọrẹ wá o Bàbá
nínú ìpèsè rẹ Bàbá
wá gb'ẹbọ wa.
VERSE 1
Bí ọrẹ Ábẹ́lì
bí ọrẹ Ábrámù
nínú ìpèsè rẹ Bàbá
wá gb'ẹbọ wa.
Ọre tí a mú wá o
lọ́wọ́ Àlùfáà rẹ
ọrẹ àtinú wá ni
Ọrẹ àtokàn wa ni
VERSE 2
Búrẹ́dì tí a mú wá
Yí ò dara à rẹ
otí tí a mú wá o nìyí
Yí ó dẹ̀jẹ̀ rẹ
kí ẹbọ tí a rú sí ọ lọ́wọ́ yìí
kí ó wù ọ́ o
ọrẹ tí a mú wá o nìyí
wa gbẹbọ wa.
VERSE 3
Ẹbọ wa, Ẹbọ wa
la wá rúbọ o
Kí a lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà
níwájú rẹ.
Ẹbọ wa, Ẹbọ wa
la wá rúbọ o
Kí a lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà
níwájú rẹ.
pẹlu 're le a ti e mi 'ro nu pi wa da
la wa ru bo o
Kí a lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà
níwájú rẹ.
ki e bo ti a ru si o lo ni i
ki o wu o o
Kí a lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà o
níwájú rẹ.