KERE O (A Christmas Song) by Ademola Adeosun — Lyrics

Ademola Adeosun Yoruba Christmas Hymns Solfa notation

Full Lyrics

Kéré o, ara ẹ yọ, ìgbàlà ti dé Kéré o, ara ẹ yọ, ìtura ti dé Kéré o, t'ọmọdé t'àgbà, ìwòsàn ti dé Kéré o, kéré o Kéré o, a bí Jésù fún wa A ti bí, a bí, a ti bí A ti bí, a bí Jésù fún wa A b'Olùgbàlà fún wa o, a ti bí, o, ara ẹ yọ Olùgbàlà aráyé la bí fún wa, a ti bí, o, ara ẹ yọ A b'Olùgbàlà fún wa, a ti bí, o, ara ẹ yọ Yọ, a ti bí, a ti bí, a bí Jésù fún wa Ìràwọ̀ kan yọ Ìràwọ̀ kan yọ, l'ọ́gànjọ́, ìràwọ̀ kan yọ O yọ, o yọ, ìràwọ̀ kan yọ, l'ọ́gànjọ́, ìràwọ̀ kan yọ Ìràwọ̀ kan yọ, l'ọ́gànjọ́, ìràwọ̀ kan yọ O yọ, o yọ, ìràwọ̀ kan yọ, l'ọ́gànjọ́, ìràwọ̀ kan yọ L'ọ́gànjọ́, àwọn amòye rí, wọ́n tẹ̀lé, ìràwọ̀ kan yọ O yọ, o yọ, ìràwọ̀ kan yọ, l'ọ́gànjọ́, ìràwọ̀ kan yọ Ìràwọ̀ kan yọ, l'ọ́gànjọ́, ìràwọ̀ kan yọ O yọ, o yọ, àwọn amòye rí, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n wá tẹríba fún wọn MALE CANTORS Wúrà mi rèé CHOIR Ká fi dá lọ́lá, ẹ wá ká fi jó kí, kí ọmọ Màríà, ká lọ sọ ẹ l'ọ́ba CANTORS Tùràrí mi rèé, Òjíá mi rèé CHOIR Ká fi dá lọ́lá, ba ká fi jó kí Ká fi dá lọ́lá, ọmọ titun, ká sọ ẹ l'ọ́ba Ẹ dìde ará, ẹ dìde ká lọ kí, Ọba ta bí fún wa OSTINATO Ká lọ dá lọ́lá, Ọba ni o, a dá lọ́lá, Ẹmánúẹ́lì, l'órúkọ rẹ̀ SOPRANO SOLI Ọba aládé, Ọba ìyè, Ọba òtítọ́, Olùràpadà Jésù Kírísítì a bí, ọmọ Ọlọ́run ni, Ọba òtítọ́, Olùràpadà Wá ẹ yọ o, eh! ẹ yọ o eh! A ti bí fún wa, Ọba òtítọ́, Olùràpadà Wá eh e e e e e e, Ọba ológo Ah a a a ah, Olùràpadà, wá.

Download the sheet music

KERE O (A Christmas Song)

KERE O (A Christmas Song)

By Ademola Adeosun
Solfa
Yoruba
3 pages
8 Downloads
Christmas Hymns
0 0

More lyrics you may want