Full Lyrics
[Maestoso]
A ti rí ìràwọ̀ ogo,
ìdunnu ṣi ti kún aye.
Ayọ, ayọ, ayọ, ayọ, ayọ ni l'aye.
Ayọ, ayọ, ayọ!
Awọn angẹli n kọrin;
Ayọ, ayọ, ayọ, ayọ ni l'aye.
Ayọ. Ayọ. Ayọ, awa naa n kọrin.
Káàbọ Ọba awọríọba, káàbọ.
Káàbọ Olùgbàlà aráyé,
Káàbọ, Ìmọ́lẹ̀ ayérayé;
O, káàbọ Ọba awọríọba,
Káàbọ Olùgbàlà aráyé,
Káàbọ, Ìmọ́lẹ̀ ayérayé.
[Energico]
Ayọ! Ayọ! Ayọ! Ayọ!
Onigbagbọ ẹ yọ, ẹ yọ!
Alade ogo ti wa s'aye, o de!
T'iyanu, t'ibukun l'o de o, o de!
Araye ẹ wa k'a lọ f'iba fun;
Ọba 'wa, alaafia l'o mu de o,
Atẹrẹrẹ k'ari aye o, o de o!
Araye ẹ wa k'a lọ f'iba fun.
Imanuwẹli O,
Káàbọ Ọba awọríọba,
Káàbọ Ọba, káàbọ.
Káàbọ Olùgbàlà aráyé,
Káàbọ, Ìmọ́lẹ̀ ayérayé.
[Baritone Solo]
N'inú ẹṣẹ ni awa ti n gbe,
kosi ẹda kankan to wa gba 'wa,
afi Ọmọba ayérayé;
Jesu Kristi, Mesaya, ti de!
[Allegretto a gioioso]
Ehm! Ọba nla awa, Ọba!
Ọba mimọ, Ọba mimọ,
Ọba nla awa, Ọba!
Oun l'Ọba!
Ọba nla awa ni, Ọba!
[Tenor Solo]
Ọba as'ọrọ t'iṣe t'iṣe,
alaṣẹ l'aye, alaṣẹ l'ọrun,
Ọn'iyẹ mimọ. Káàbọ!
Ọba adani magbagbe ẹni,
amọni d'enu ni Ọba,
Oniṣe mimọ o, Káàbọ!
Af'unni masiregun l'ode,
abi s'oorẹ kandu kandu,
Ol'ọkan mimọ o, Káàbọ! Ah! Ah!
Ẹ ku ile 'n juba Rẹ,
ẹ ku ọkọ n yin o,
talo le sin Ọ to,
Ọba titi aye, Kabiyesi,
Ọba nla awa,
Ọba mimọ, Ọba mimọ,
Ọba ogo, Ọba ogo,
Ọba nla awa,
Ọba nla awa ni,
Ọba nla awa ni,
Ọba nla awa ni.
Iwọ l'Ọba!
Ọba adani ni ifẹ ẹ ni,
Ọba to wa lati ku fun ẹni,
Ọba titi aye, Kabiyesi,
Ọba mimọ, Ọba mimọ,
Ọba ogo, Ọba ogo,
Iwọ l'Ọba!
Ọba nla awa ni,
Ọba nla awa ni,
ap'ẹni k'ẹni ni o, Eh!
Ọba mimọ, Ọba toto,
Ọba nla awa, Ọba!
Ọba titi aye,
Ọba nla awa,
Ọba mimọ, Ọba mimọ,
Ọba nla awa ni,
Ọba nla awa ni,
Ọba nla awa ni,
awa n juba Rẹ,
Ọba iba, iba o!
Kabiyesi,
Ọba nla awa, Ọba!
Ọba ogo, Ọba ogo,
Ọba nla awa!
Ọba nla awa ni,
Ọba nla awa ni,
Ọba nla awa ni,
Ọba nla awa ni.
[Andante Maestoso]
Káàbọ, Ìmọ́lẹ̀ ayérayé.