Full Lyrics
Iwọ ni Alufaa titi lai;
Alufaa bi Mẹlkisẹdẹki atijọ.
Ojiṣẹ Oluwa, Ọga ogo.
Ki Oluwa tọ ẹsẹ yin s'ọna,
ki o si mu apa ọwọ yin l'arale.
Ki Baba pẹ fun wa;
Oluwa da Baba si fun wa.
fun ẹmi Baba wa.
A yin Ọ fun iṣẹ nla t'O ti ṣe fun wa.
Oyigiyigi, jọwọ jẹ amọna wọn.
Awimayẹhun, dakun jẹ abo wọn.
Olubukun l'Oluwa, Ọlọrun Israeli.
Ẹnikanṣoṣo ti n s'ohun Iyanu.
Ibukun ni fun orukọ rẹ ti'o l'ogo titi lai!
Ki gbogbo aye kun fun ogo rẹ.
Yin Oluwa.
Kabiyesi Oluwa, mẹtalọkan, O wi bẹṣebẹ!
Ẹlẹda Akọda aye, Aṣẹda Ọrun!
Ọba t'o mọ mi, Ọba t'o mọ ọ, Ọba t'o mọ wa, Ọba to mọ wa.
Gbanigbanini' jogunle.
Aduro gbọingbọin lẹhin aṣotọ!
Arugbo ọjọ, Ọgbagba tin gbara adugbo!
Akikitan.
Yin Baba, Ọga ogo.
Oluwa da Baba si fun wa.
da Baba wa, da Baba si fun wa,
Oluwa da Baba si fun wa.
Amin.