Full Lyrics
SOLO
Apejọpọ l'ọjọ oni
Lati wa yin Ọ Baba,
Jẹ ki Ẹmi rẹ ko sọkalẹ wa le wa lori.
Baba Mimọ a de o, wa ṣaanu fun wa.
CHORUS
Baba Mimọ a de o, a de!
Wa ṣaanu fun wa.
A de! siwaju itẹ rẹ
Apejọpọ l'orukọ rẹ.
Baba Mimọ foriji wa.
Baba Mimọ a de o, a de!
Wa ṣaanu fun wa.
Gbogbo ẹṣẹ ti a ṣe
Ki isin wa oni jẹ atẹwọgba.
Baba Mimọ a de o, a de!
Wa ṣaanu fun wa.
DUET
Baba Mimọ! Baba Mimọ! Baba Mimọ!
Wa ṣaanu fun wa. A de!
CHORUS
Baba Mimọ a de o, a de!
Wa ṣaanu fun wa.
Jọwọ wa ṣaanu fun wa.
Baba Mimọ a de o, a de!
Wa ṣaanu fun wa.