Full Lyrics
CHORUS
Ara e dide e ba mi jo;
Eniyan mi e ba mi yo;
Oluwa mi lo gbe mi ga.
VERSE 1
Ninu ohun gbogbo, O pa mi mo;
Ninu ewu gbogbo, O mu mi ye.
Kilo tun ye mi bi ko se ope,
Ope ni t'emi l'ojo gbogbo.
VERSE 2
O wa f'ire gbogbo da mi l'ola;
O tun f'ohun rere t'o tun ga ju,
T'o m'aye ye mi, t'o m'orun ye mi.
B'ori ayo mi l'ojo gbogbo.
VERSE 3
O tun f'omo rere da mi l'ola;
O mu mi j'oba s'inu ayo;
Modupe, modupe, Baba O se,
E ba mi yo, mo dupe jojo.
VERSE 4
O fe gbogbo won d'oju iku,
O mu gbogbo wa de'le ayo;
Kil'o tun ye mi bi ko se ope;
Ope, iyin ni f'Oluwa wa.
VERSE 5
Oluwa rere t'o s'aye pe;
Oruko Baba la maa yin;
B'aye gb'ogun de, Jesu ni mo ni;
Ope ni t'emi l'ojo gbogbo.
VERSE 6
Tewo gba ore ti mo mu wa,
Ni o se ohun t'o tun ga ju;
L'aye ti mo ni t'emi, t'ara;
Ope ni t'emi l'ojo gbogbo.
VERSE 7
B'o ba ti yeni lo ye k'a wi;
Oruko rere lo pe wa ju;
Eni t'o n'ola lo ns'ohun ola;
A o ma yo ni l'ojo gbogbo.