Full Lyrics
INTRO
A dúpẹ́ fún ohun tí ẹ ṣe fún wa
Ore rẹ nínú ayé wa ó máa pọ̀
Olùfẹ́ ṣe, ẹ ṣe Olùgbàlà
A dúpẹ́ o
REFRAIN
Gbọ́pé wa Bàbá
Gbọ́ pé wa o
Yìn àt'ògo ló yẹ ó o Bàbá
Fún ore rẹ o o
A dúpẹ́ o Bàbá
UNISON
Àwa la ti dúpẹ́ ìyànu rẹ
Lórí wa, ẹ ṣe Bàbá a dúpẹ́ o
Ọba wa ẹ ṣe Ọba wa
Ló ti wa, ẹ ṣe o Bàbá o a dúpẹ́ o
Ọba ẹ ṣe o Ọba wa
VERSE 1
Gbogbo iye tí a ní láyé
Bàbá láti ọ̀dọ̀ rẹ ló ti wá
Ọba mímọ́, Ọba Òkè,
Olú Ọ̀run, Olùbùkún
Olùtọ́jú a gbé ọ ga
VERSE 2
Àwa ọmọ aráyé a wá dúpẹ́
Ore àná, a dúpẹ́ ore òní,
A tún dúpẹ́ ore ọ̀la
Gbọ́pé Bàbá wa, gbọ́pé Ọmọ,
Gbọ́pé o o Ẹ̀mí Mímọ́, wá gbọ́pé Bàbá
Aládé Ògo a dúpẹ́ ore rẹ
VERSE 3
Kábíyèsí Bàbá, Èlédùmarè
Ọba a wá dúpẹ́ ore
Olùgbèjà, Ọba tótó, ẹlẹ́dàá wa o o
Ọba a wá dúpẹ́ ore
Olùpèsè, Ọba pípé awímáyẹhùn o
Ọba a wá dúpẹ́ ore
Olùgbàlà, Ọba ayé àtọ́fàrátì o
Ọba a wá dúpẹ́ ore
A wá dúpẹ́ ore