Full Lyrics
CHORUS
A f'ọpẹ f'Ọlọrun isin ti pari a dupẹ
A f'ọpẹ f'Ọlọrun Baba wa a dupẹ o
Pẹlu ayọ ninu ọkan wa
A kuro ni'le Oluwa sin wa de'le
Baba wa sin wa de'le
VERSE 1
A dupẹ fun Ọ a si gba agbara nipa rẹ
Ti a ti gbọ ọrọ rẹ fun iye
A mu iroyin ifẹ Ọlọrun lọ fun gbogbo eniyan
VERSE 2
Igbagbọ wa ti gba wa la Oluwa ti pe wa lati sin
Bi a ṣe n sin pẹlu igbesi aye ti a n gbe
Ki a le dari awọn eniyan Ọlọrun pada s'ọdọ Rẹ
Fun ogo orukọ Rẹ
CODA
Ki Oluwa bukun fun wa, k'o si pa wa mọ
Ki ojurere Rẹ mọlẹ s'wa lara
Ki ibukun Ọlọrun Baba ti Ọmọ ati Ẹmi Mimọ ma ba wa gbe
Lai ati lailai
Amin