Full Lyrics
[REFRAIN]
Ogo, Ogo alleluia, alleluia,
Ogo, Ogo alleluia, alleluia,
F'Olorun l'oke Orun.
[VERSE 1]
Ogo ni f'Olorun l'oke orun,
Alafia l'aiye f'awon eniyan re,
Awon eniyan to nifinu rere,
Ogo ni f'Olorun.
[VERSE 2]
Awa yin O, awa f'ibukun fun O,
Awa yin O l'ogo Olorun baba,
Adupe nitori Ogo nla re,
F'Olorun l'oke Orun.
[VERSE 3]
Oluwa Olorun Oba Orun,
Olorun Oba Eledumare,
Oluwa Jesu Kristi Omo'orun
L'orun kan soso.
[VERSE 4]
Oluwa Olorun Odo agutan,
Omo ti Baba to ko ese aiye lo,
Jowo jare wa saa anu fun wa
tori ese wa.
[VERSE 5]
Iwo l'eni to ko ese aiye lo,
Fiye denu gbo adura wa,
Iwo l'eni to ko ese aiye lo,
Jowo saanu fun wa.
[VERSE 6]
Iwo Jesu Kristi Oluwa Mimo,
Iwo nikan ni Oga ju lo,
Pelu Emi Mimo ebun ife,
Ninu Ogo l'orun.