OGO LO YE BABA [GLORIA] by Ogunlade Chris — Lyrics

Ogunlade Chris Yoruba Gloria Solfa notation

Full Lyrics

INTRO Kí l'ó yẹ f'Ọlọ́run Ògo f'Ọlọ́run Ògo f'Ọlọ́run Ògo ló yẹ ọ́ o Bàbá CHORUS Ògo fún Ọlọ́run l'ọ́run o Àlàáfíà f'áwọn ènìyàn rẹ̀ l'áyé F'áwọn ènìyàn rẹ̀ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run Ọba Ọlọ́run ọ̀run Ògo yẹ fún Ọba VERSE 1 A yìn ọ́ A f'ọpẹ́ fún ọ Àwa forí wa balẹ̀ Jésù Kírísítì Ọmọ bíbí Bàbá Ìwọ t'ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ Wá ṣàánú fún wa Jésù Ọba Ọlọ́run ọ̀run Ògo yẹ fún Ọba VERSE 2 Ẹni t'ó jókòó l'ọ́wọ́ ọ̀tún Bàbá Ṣàánú fún wa O Bàbá Ṣèbí Ìwọ nìkan ni mímọ́ Bàbá Ìwọ nìkan l'Olúwa Ìwọ nìkan l'ọ́gá jùlọ o Ọba Ọlọ́run ọ̀run Ògo yẹ fún Ọba VERSE 3 Ìwọ Jésù Kírísítì Pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ o Nínú ògo Ọlọ́run Àmín àṣẹ kó ṣẹ Àmín

Download the sheet music

OGO LO YE BABA [GLORIA]

OGO LO YE BABA [GLORIA]

By Ogunlade Chris
Solfa
Yoruba
2 pages
2 Downloads
Gloria
0 0

More lyrics you may want