Full Lyrics
TENOR I
A ti ri irawọ ogo Idunnu si ti kun aye.
Ayọ, ayọ, ayọ, ayọ ni l'aye.
SOPRANO
Ayọ, kun ọrun, ayọ ni l'aye.
Kaabọ Ọba awọn ọba,
Kaabọ Olugbala araye,
kaabọ imọlẹ ayeraye.
Imanuwẹli o, Kaabọ Ọba awọn ọba,
Kaabọ Olugbala araye,
kaabọ imọlẹ ayeraye.
Ẹ yọ! O de! O de o!
Ar'aye ẹ wa k'a lọ f'iba fun.
O ti wa lati sọ wa d'ọtun,
Ọba' wa, alaafia l'o mu de o,
Atẹrẹrẹ kari aye o,
O de o! Ar'aye ẹ wa k'a lọ f'iba fun.
Imanuwẹli o, Kaabọ Ọba awọn ọba,
Kaabọ Olugbala araye,
kaabọ imọlẹ ayeraye.
BARITONE SOLO
Ninu ẹsẹ ni awa ti n gbe;
kosi Ẹda kankant'o wa gba' wa,
Afi Ọm'ọba ayeraye;
JesuKristi, Mesaya ti de.
TENOR SOLO
Ọba titi aye kabiyesi Ọba nla awa Ọba.
Ọba as'ọrọ t'asẹ t'asẹ,
Al'asẹ l'aye, Al'asẹ l'ọrun,
oniyemi mọ kaabọ!
Ọba adanimagbagbe eni
amọ' ni denu ni Ọba,
on'ise mimọ o, kaabọ!
Afunni ma si regun l'ode,
Abi s'oore kandu kandu,
Ọl'ọkan mimọ o, kaabọ! Ah! Ah!
Eku ile'n ju' ba Rẹ,
eku oko n yin Ọ o.
Ta lo le sin Ọ to, Oba?
I wọ l'ọba!
Ọba adani ni ifẹ ẹni,
Ọba t'o wa la ti ku fun ẹni,
A p'ẹni kẹ' ni ni o. Eh!
Ọba mimọ, Ọba toto,
awa n ju' ba Rẹ,
Ọba iba, iba o!
SOPRANO
Kaabọ Ọba awọn ọba,
Kaabọ Olugbala araye,
kaabọ imọlẹ ayeraye.
Imanuwẹli o, Kaabọ Ọba awọn ọba,
Kaabọ Olugbala araye,
kaabọ imọlẹ ayeraye.