Full Lyrics
Ah e Iya! Iya nla! Jesu mi jiya nitori ẹṣẹ wa
Jesu mi jiya nitori ẹṣẹ wa
Jesu jiya fun wa o ninu ọgba Gẹsẹmani
Jesu gbadura pe ki ago iya rẹ kọja
Baba bo ba ṣe fẹ rẹ, dakun jẹ ki ago iya yi kọja lori mi
Wọn fa Jesu lọ s'ọdọ Pọnti Pilatu
Wọn fa lasọ ya o, wọn fa lasọ ya
Wọn fi ṣe yẹyẹ o, wọn fi ṣe yẹyẹ
Wọn tu itọ s'oju rẹ, wọn faa le ori lẹ o, wọn gbe ade ẹgun s'ori rẹ
Wọn lu u bi ole o, ṣugbọn o farada nitori ifẹ rẹ fun araye
Ẹṣẹ wa lo kan Jesu mọ igi agbelebu, dakun
Dariji wa o Baba, a wambẹ o
Dariji wa o Baba, a wambẹ o
Ọdọ agutan Ọlọrun t'ọn ko ẹṣẹ araye lọ, ṣaanu fun wa o, a ko ni dẹṣẹ mọ
Dariji wa o Baba, a wambẹ o
Ara igbala de nipasẹ iku Jesu Kristi fun wa o, jẹ ki mi ni igbala yi
L'ọra wa pada, a gbada
O ṣe o Baba fun ifẹ rẹ si ẹlẹṣẹ bi tawa, pa ọkan wa mọ ni alaafia pẹlu ri iye aiyeraiye
Amin, Amin, Amin, Amin