Full Lyrics
CANTOR
Ògo ni f'Ọlọ́run l'ókè ọ̀run
UNISON
Àlàáfíà sì ni l'áyé f'áwọn ẹ̀dá onínú rere.
CHORUS
Ara ẹ gbé ga
Ara, Ara ẹ gbé ga
Ọpẹ́ yẹ f'Ọlọ́run
Ìyìn yẹ f'Ọlọ́run
Ògo yẹ, Ògo yẹ, Ògo yẹ f'Ọlọ́run wa
Ara f'Ọlọ́run wa
Àmín.
VERSE 1
Baba wa a gbé ọ ga
A f'íyìn àt'ògo fún ọ
VERSE 2
Oluwa Ọlọrun wa
Ọlọrun Ọdọ Aguntan Ọlọrun
Iwọ to n ko ẹṣẹ aye lọ
Ṣaanu fun wa gbọ tiwa
VERSE 3
Iwọ nikan l'ẹni mimọ
Oluwa to ga julọ
Jesu Ọmọ Baba
Ninu iṣọkan Ẹmi Mimọ