Full Lyrics
[VERSE 1]
Olúwa, mo wá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìfọ̀yà ọkàn
Ọmọ rẹ ni mí, Ọlọ́run àánú àti ojurere
[CHORUS]
Bàbá, mo bẹ̀bẹ̀ fún àánú
Sàánú, sàánú fún mi o
Olúọ̀run, mo bẹ̀ ọ́ o
Sàánú, sàánú fún mi o
Bàbá, mo bẹ̀bẹ̀ fún àánú
[VERSE 2]
Adákẹ́dájọ́ mo kígbe pè ọ́ o
Mò ń bẹ̀bẹ̀ o pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ
Nípa ìrànlọ́wọ́ oore ọ̀fẹ́ rẹ
Alágbádá iná, mi ò ní dẹ́ṣẹ̀ mọ́
[VERSE 3]
Ràn mí lọ́wọ́ o láti má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́
Ìwọ nìkanṣoṣo ni mo ṣẹ̀ sí Olúwa
Má ṣe lé mi kúrò níwájú rẹ Ẹlẹ́dàá mi
Dá aìyà titun sínú ọkàn mi o
Mú mi wá sọ́dọ̀ rẹ Olúwa mi, mo bẹ̀ ọ́ o
[CODA]
Arínúróde ṣàánú o
Olúwa mi ṣàánú
Alákóso ọ̀run Bàbá mo ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ
Dárí ji ẹ̀ṣẹ̀ mi o
Ọlọ́run mi ṣàánú