Full Lyrics
VERSE 1
Ọkunkun pim pim, atẹgun fẹrẹfẹ,
Imọlẹ yanyan, ina laulau
Gbogbo nkan tẹ da o, awa le fun.
Gbogbo nkan tẹ ṣe, awa le ṣe fun baba
Ki lati ri ki la mọ, baba?
Ẹyin l'ọba awọn ọba,
Alagbara ara! Alagbara ara! E!
CHORUS
Iba o! Iba f'Olu ọrun
Iba o! Iba f'Olu ọrun
Iba f'Olu ọrun
VERSE 2
Ẹbun wo lo ju ẹbun rẹ lọ? Kosi! rara
Afunnimasiregun
Oluwa, ẹ ṣe o! Ọlọrun ọba adupẹ o!
Fun ẹbun idunu to peye,
Fun ẹbun imọ tafi yege
VERSE 3
Ẹ bawa gbega o!
Ọlọrun Ọlọrun Ọlọrun aleferopedarun.
Ọba titi! Ọba toto
Ọba wa toju igba lailai
Alaṣẹ aye iba rẹ! Alaṣẹ ọrun iba rẹ!
Olumọrankan iba rẹ
Iba!
TENOR SOLO
Ọba'yeraye, iba rẹ! Iba rẹ!