ONA-OPE MI OPO by ADEREMI OLATIBE — Lyrics

ADEREMI OLATIBE Yoruba Offertory Hymns Solfa notation

Full Lyrics

[CHORUS] Ọna ọpẹ mi o, o pọ jọjọ, O pọ, o pọ o pọ jọjọ. A wa juba niwaju rẹ, Ki ọpẹ ko se tẹwọgba. A wa siwaju rẹ, Lati wa fi ọpẹ to yẹ fun ọ, Baba mimọ. Gba lọwọ wa, ki ibukun ko jẹ ti wa. Gba lọwọ wa, ki ibukun ko jẹ ti wa. [VERSE 1] A dupẹ, wa gbọ pẹ wa. A wa juba fun O o, A wa wolẹ fun O o, A tun de loni o, Gbọ pẹ wa, gbọ pẹ wa. [VERSE 2] Ẹ jẹ ka lọ siwaju Oluwa, Ẹ jẹ ka lọ, ẹ ma se bẹru. Ẹ jẹ ka lọ yin logo, Ẹ jẹ ka lọ nitori pe Oun lo da gbogbo aiye, T'o gbe ilẹ kalẹ l'ori omi, T'o ni ilẹ ati ẹkun rẹ. O ko wa yọ ninu Ẹmi Mimọ, O pa wa mọ ninu ibi gbogbo, Fun eyi at' awọn t'o mọ, Gbọ pẹ wa.

Download the sheet music

ONA-OPE MI OPO

ONA-OPE MI OPO

By ADEREMI OLATIBE
Solfa
Yoruba
2 pages
5 Downloads
Offertory Hymns
0 0

More lyrics you may want